9Àwọn tí ó wà ní aginjù yóò tẹríba fún un àwọn ọ̀tá rẹ̀ yóò máa lá erùpẹ̀ ilẹ̀.
10Àwọn ọba Tarṣiṣi àti ti erékùṣù wọn yóò mú ọrẹ wá fún un; àwọn ọba Ṣeba àti Seba wọn ó mú ẹ̀bùn wá fún un.
11Gbogbo ọba yóò tẹríba fún un àti gbogbo orílẹ̀-èdè yóò sìn ín.
12Nítorí yóò gba àwọn aláìní nígbà tí ó bá ń ké, tálákà àti ẹni tí kò ní olùrànlọ́wọ́.
13Yóò káàánú àwọn aláìlera àti aláìní yóò pa aláìní mọ́ kúrò nínú ikú.