6Yóò dàbí òjò tí ó ń rọ̀ sórí pápá ìrẹ́mọ́lẹ̀, bí ọwọ́ òjò tó ń rin ilẹ̀.
7Àwọn olódodo yóò gbilẹ̀ ni ọjọ́ rẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà yóò sì wà; títí tí òṣùpá kò fi ní sí mọ́.
8Yóò máa jẹ ọba láti òkun dé òkun àti láti odò Eufurate títí dé òpin ayé.
9Àwọn tí ó wà ní aginjù yóò tẹríba fún un àwọn ọ̀tá rẹ̀ yóò máa lá erùpẹ̀ ilẹ̀.
10Àwọn ọba Tarṣiṣi àti ti erékùṣù wọn yóò mú ọrẹ wá fún un; àwọn ọba Ṣeba àti Seba wọn ó mú ẹ̀bùn wá fún un.