Saamu 78

Wọn kò pa májẹ̀mú Ọlọ́run mọ́ wọn sì kọ̀ láti máa gbé nínú òfin rẹ̀.

Psalm 78:10 (UKJV) They kept not the covenant of God, and refused to walk in his law;

8Kí wọn kí ó má ṣe dàbí àwọn baba ńlá wọn, ìran alágídí àti ọlọ́tẹ̀, ìran tí ọkàn wọn kò ṣọ òtítọ́ si olóore, àti ẹ̀mí ẹni tí kò bá Ọlọ́run dúró ṣinṣin.

9Àwọn ọkùnrin Efraimu, tí ó há mọ́ ọ tí wọ́n mú ọrun, wọ́n yípadà ní ọjọ́ ogun

10Wọn kò pa májẹ̀mú Ọlọ́run mọ́ wọn sì kọ̀ láti máa gbé nínú òfin rẹ̀.

11Wọ́n gbàgbé ohun tí ó ti ṣe, àwọn ìyanu tí ó ti fihàn wọ́n.

12Ó ṣe ìyanu níwájú àwọn baba wọn ní ilẹ̀ Ejibiti, ní agbègbè Ṣoani.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.