Saamu 89

Olúwa, níbo ni ìṣeun ìfẹ́ rẹ àtijọ́ wà, tí ìwọ ti fi òtítọ́ rẹ búra fún Dafidi?

Psalm 89:49 (UKJV) Lord, where are your former loving kindnesses, which you sware unto David in your truth?

47Rántí bí ọjọ́ mi ti kúrú tó nítorí asán ha ni ìwọ fi ṣẹ̀dá àwọn ènìyàn!

48Ta ni yóò wà láààyè tí kò ní rí ikú rẹ̀? Ta ló lè sá kúrò nínú agbára isà òkú?

49Olúwa, níbo ni ìṣeun ìfẹ́ rẹ àtijọ́ wà, tí ìwọ ti fi òtítọ́ rẹ búra fún Dafidi?

50Rántí, Olúwa, bí a ti ń gan àwọn ìránṣẹ́ rẹ; bí èmi ti gbà ní àyà mi láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn,

51ẹ̀gàn tí àwọn ọ̀tá rẹ gàn, Olúwa, tí wọn gan ipasẹ̀ ẹni àmì òróró rẹ.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.