Saamu 94

Wọ́n kó ara wọn jọ sí olódodo wọ́n sì ń dá àwọn aláìṣẹ̀ lẹ́bi sí ikú.

Psalm 94:21 (UKJV) They gather themselves together against the soul of the righteous, and condemn the innocent blood.

19Nígbà tí àníyàn ńlá wà nínú mi, ìtùnú rẹ̀ mú ayọ̀ sí ọkàn mi.

20Ìjọba ìbàjẹ́ ha lè kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú rẹ ẹni tí ń fi òfin dì mọ́ ìwà ìkà?

21Wọ́n kó ara wọn jọ sí olódodo wọ́n sì ń dá àwọn aláìṣẹ̀ lẹ́bi sí ikú.

22Ṣùgbọ́n, Olúwa ti di odi alágbára mi, àti Ọlọ́run mi ni àpáta nínú ẹni tí mo ti ń gba ààbò.

23Òun yóò san ẹ̀san ibi wọn fún wọn yóò sì pa wọ́n run nítorí búburú wọn Olúwa Ọlọ́run wa yóò pa wọ́n run.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.