1Olúwa Ọlọ́run ẹni tí ń gbẹ̀san, Ọlọ́run ẹni tí ń gbẹ̀san.
2Gbé ara rẹ sókè, ìwọ onídàájọ́ ayé; san ẹ̀san fún agbéraga ohun tí ó yẹ wọ́n.
3Báwo ní yóò ti pẹ́ tó, Olúwa tí àwọn ẹni búburú yóò kọ orin ayọ̀?
4Wọ́n ń sọ̀rọ̀ ìgbéraga jáde; gbogbo àwọn olùṣe búburú kún fún ìṣògo.
5Wọ́n fọ́ àwọn ènìyàn rẹ túútúú, Olúwa: wọ́n pọ́n ilẹ̀ ìní rẹ̀ lójú.