5Wọ́n fọ́ àwọn ènìyàn rẹ túútúú, Olúwa: wọ́n pọ́n ilẹ̀ ìní rẹ̀ lójú.
6Wọ́n pa àwọn opó àti àlejò, wọ́n sì pa àwọn ọmọ aláìní baba.
7Wọ́n sọ pé, “Olúwa kò rí i; Ọlọ́run Jakọbu kò sì kíyèsi i.”
8Kíyèsi i, ẹ̀yin aláìlóye nínú àwọn ènìyàn; ẹ̀yin aṣiwèrè, nígbà wo ni ẹ̀yin yóò lóye?
9Ẹni tí ó gbin etí, ó lè ṣe aláìgbọ́ bí? Ẹni tí ó dá ojú? Ó ha lè ṣe aláìríran bí?