Ìfihàn 16

Ẹ̀kẹta sì tú ago tirẹ̀ sínú odò, àti sí orísun àwọn omi; wọ́n sì di ẹ̀jẹ̀.

Revelation 16:4 (UKJV) And the third angel poured out his vial upon the rivers and fountains of waters; and they became blood.

2Èkínní sì lọ, ó sì tú ago tirẹ̀ sí orílẹ̀ ayé: egbò kíkẹ̀ tí ó sì díbàjẹ́ sì dá àwọn ènìyàn tí ó ní àmì ẹranko náà, àti àwọn tí ń foríbalẹ̀ fún àwòrán rẹ̀.

3Èkejì sì tú ago sínú Òkun; ó sì dàbí ẹ̀jẹ̀ òkú ènìyàn, gbogbo ọkàn alààyè sì kú nínú Òkun.

4Ẹ̀kẹta sì tú ago tirẹ̀ sínú odò, àti sí orísun àwọn omi; wọ́n sì di ẹ̀jẹ̀.

5Mo sì gbọ́ angẹli tí ó n wí pé: “Olódodo ni ìwọ ninu gbogbo ìdájọ́ wọ̀nyí, ìwọ ẹni tí ó n bẹ àti tí ó tí wa, Ẹni Mímọ́ nítorí tí ìwọ ṣe ìdájọ́ bẹ́ẹ̀.

6Nítorí tí wọ́n ti ta ẹ̀jẹ̀ àwọn ènìyàn mímọ́ àti ti àwọn wòlíì sílẹ̀, ìwọ sì fi ẹ̀jẹ̀ fún wọn mu; èyí yìí ní ó yẹ wọ́n.”

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.