Orin Solomoni 3

Èmi yóò dìde nísinsin yìí, èmi yóò sì rìn lọ káàkiri ìlú, ní àwọn òpópónà àti ní àwọn gbangba òde; èmi yóò wá ẹni tí ọkàn mi fẹ́. Bẹ́ẹ̀ ni mo wá a ṣùgbọ́n èmi kò rí i.

Song of Solomon 3:2 (UKJV) I will rise now, and go about the city in the streets, and in the broad ways I will seek him whom my soul loves: I sought him, but I found him not.

1Ní orí ibùsùn mi ní òru mo wá ẹni tí ọkàn mí fẹ́; mo wá a, ṣùgbọ́n èmi kò rí i.

2Èmi yóò dìde nísinsin yìí, èmi yóò sì rìn lọ káàkiri ìlú, ní àwọn òpópónà àti ní àwọn gbangba òde; èmi yóò wá ẹni tí ọkàn mi fẹ́. Bẹ́ẹ̀ ni mo wá a ṣùgbọ́n èmi kò rí i.

3Àwọn ọdẹ tí ń ṣọ́ ìlú rí mi bí wọ́n ṣe ń rìn yíká ìlú. “Ǹjẹ́ ìwọ ti rí ẹni tí ọkàn mi fẹ́?”

4Gẹ́rẹ́ tí mo fi wọ́n sílẹ̀ ni mo rí ẹni tí ọkàn mi fẹ́. Mo dìímú, èmi kò sì jẹ́ kí ó lọ títí tí mo fi mú u wá sílé ìyá mi, sínú yàrá ẹni tí ó lóyún mi.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.