4Gẹ́rẹ́ tí mo fi wọ́n sílẹ̀ ni mo rí ẹni tí ọkàn mi fẹ́. Mo dìímú, èmi kò sì jẹ́ kí ó lọ títí tí mo fi mú u wá sílé ìyá mi, sínú yàrá ẹni tí ó lóyún mi.
5Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerusalẹmu, mo fi àwọn abo egbin àti abo àgbọ̀nrín igbó fi yín bú kí ẹ má ṣe rú olùfẹ́ mi sókè kí ẹ má sì ṣe jí i títí yóò fi wù ú.
6Ta ni ẹni tí ń ti ijù jáde wá bí ọ̀wọ̀n èéfín tí a ti fi òjìá àti tùràrí kùn lára pẹ̀lú gbogbo ìpara olóòórùn oníṣòwò?
7Wò ó! Àkéte rẹ̀ tí í ṣe ti Solomoni, àwọn akọni ọgọ́ta ni ó wà yí i ká, àwọn akọni Israẹli,
8gbogbo wọn ni ó mú idà lọ́wọ́, gbogbo wọn ní ìmọ̀ nínú ogun, idà oníkálùkù wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, wọ́n múra sílẹ̀ fún ìdágìrì òru