4Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Aaroni àti àwọn ọmọ Lefi tí Dafidi péjọ papọ̀.
5Ọgọ́fà nínú àwọn ọmọ Kohati; Urieli olórí àti àwọn ẹbí rẹ̀.
6Igba ó lé ogún nínú àwọn ọmọ Merari; Asaiah olórí àti àwọn ẹbí rẹ̀.
7Àádóje nínú àwọn ọmọ Gerṣoni; Joẹli olórí àti àwọn ẹbí rẹ̀.
8Igba nínú àwọn ọmọ Elisafani; Ṣemaiah olórí àti àwọn ẹbí rẹ̀.