39Asariah sì ni baba Helesi, Helesi ni baba Eleasa,
40Eleasa ni baba Sismai, Sismai ni baba Ṣallumu,
41Ṣallumu sì ni baba Jekamiah, Jekamiah sì ni baba Eliṣama.
42Àwọn ọmọ Kalebu arákùnrin Jerahmeeli: Meṣa àkọ́bí rẹ̀, ẹni tí ó jẹ́ baba fún Sifi, àti àwọn ọmọ rẹ̀ Meraṣa, ẹni tí ó jẹ́ baba fún Hebroni.
43Àwọn ọmọ Hebroni: Kora, Tapua, Rekemu, àti Ṣema.