6Dafidi sì pín àwọn ọmọ Lefi sí ẹgbẹgbẹ́ láàrín àwọn ọmọ Lefi: Gerṣoni, Kohati àti Merari.
7Àwọn tí ó jẹ́ ọmọ Gerṣoni: Laadani àti Ṣimei.
8Àwọn ọmọ Laadani Jehieli ẹni àkọ́kọ́, Setamu àti Joẹli, mẹ́ta ní gbogbo wọn.
9Àwọn ọmọ Ṣimei: Ṣelomiti, Hasieli àti Harani mẹ́ta ní gbogbo wọn. Àwọn wọ̀nyí sì ni olórí àwọn ìdílé Laadani.
10Àti ọmọ Ṣimei: Jahati, Sina, Jeuṣi àti Beriah. Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Ṣimei mẹ́rin ni gbogbo wọn.