5Ẹgbàajì (4,000) ni kí ó jẹ́ olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà àti ẹgbàajì (4,000) ni kí o sì jẹ́ ẹni ti yóò máa yin Olúwa pẹ̀lú ohun èlò orin, mo ti ṣe èyí fún ìdí pàtàkì yìí.
6Dafidi sì pín àwọn ọmọ Lefi sí ẹgbẹgbẹ́ láàrín àwọn ọmọ Lefi: Gerṣoni, Kohati àti Merari.
7Àwọn tí ó jẹ́ ọmọ Gerṣoni: Laadani àti Ṣimei.
8Àwọn ọmọ Laadani Jehieli ẹni àkọ́kọ́, Setamu àti Joẹli, mẹ́ta ní gbogbo wọn.
9Àwọn ọmọ Ṣimei: Ṣelomiti, Hasieli àti Harani mẹ́ta ní gbogbo wọn. Àwọn wọ̀nyí sì ni olórí àwọn ìdílé Laadani.