1 Kronika 26

Meṣelemiah ní àwọn ọmọ àti àwọn ìbátan, tí ó jẹ́ alágbára méjìdínlógún ni gbogbo wọn.

1 Chronicles 26:9 (UKJV) And Meshelemiah had sons and brethren, strong men, eighteen.

7Àwọn ọmọ Ṣemaiah: Otni, Refaeli, Obedi àti Elsabadi; àwọn ìbátan rẹ̀ Elihu àti Samakiah jẹ́ ọkùnrin alágbára.

8Gbogbo wọ̀nyí ní ìran ọmọ Obedi-Edomu; àwọn àti ọmọkùnrin àti ìbátan wọn jẹ́ alágbára ọkùnrin pẹ̀lú ipá láti ṣe ìsìn náà. Ìran Obedi-Edomu méjìlélọ́gọ́ta ni gbogbo rẹ̀.

9Meṣelemiah ní àwọn ọmọ àti àwọn ìbátan, tí ó jẹ́ alágbára méjìdínlógún ni gbogbo wọn.

10Hosa ará Merari ní àwọn ọmọkùnrin: Ṣimri alákọ́kọ́ bí o tilẹ̀ jẹ́ pé kì i ṣe àkọ́bí, baba a rẹ̀ ti yàn an ní àkọ́kọ́.

11Hilkiah ẹlẹ́ẹ̀kejì, Tabaliah ẹ̀kẹta àti Sekariah ẹ̀kẹrin. Àwọn ọmọ àti ìbátan Hosa jẹ́ mẹ́tàlá ni gbogbo rẹ̀.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.