1 Kronika 26

Àwọn ọmọ Ṣemaiah: Otni, Refaeli, Obedi àti Elsabadi; àwọn ìbátan rẹ̀ Elihu àti Samakiah jẹ́ ọkùnrin alágbára.

1 Chronicles 26:7 (UKJV) The sons of Shemaiah; Othni, and Rephael, and Obed, Elzabad, whose brethren were strong men, Elihu, and Semachiah.

5Ammieli ẹ̀kẹfà, Isakari èkeje àti Peulltai ẹ̀kẹjọ. (Nítorí tí Ọlọ́run ti bùkún Obedi-Edomu).

6Ọmọ rẹ̀ Ṣemaiah ní àwọn ọmọkùnrin pẹ̀lú tí wọ́n jẹ́ olórí ní ìdílé baba a wọn nítorí wọ́n jẹ́ ọkùnrin tó lágbára.

7Àwọn ọmọ Ṣemaiah: Otni, Refaeli, Obedi àti Elsabadi; àwọn ìbátan rẹ̀ Elihu àti Samakiah jẹ́ ọkùnrin alágbára.

8Gbogbo wọ̀nyí ní ìran ọmọ Obedi-Edomu; àwọn àti ọmọkùnrin àti ìbátan wọn jẹ́ alágbára ọkùnrin pẹ̀lú ipá láti ṣe ìsìn náà. Ìran Obedi-Edomu méjìlélọ́gọ́ta ni gbogbo rẹ̀.

9Meṣelemiah ní àwọn ọmọ àti àwọn ìbátan, tí ó jẹ́ alágbára méjìdínlógún ni gbogbo wọn.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.