1 Kronika 26

Ọmọ rẹ̀ Ṣemaiah ní àwọn ọmọkùnrin pẹ̀lú tí wọ́n jẹ́ olórí ní ìdílé baba a wọn nítorí wọ́n jẹ́ ọkùnrin tó lágbára.

1 Chronicles 26:6 (UKJV) Also unto Shemaiah his son were sons born, that ruled throughout the house of their father: for they were mighty men of valour.

4Obedi-Edomu ni àwọn ọmọkùnrin pẹ̀lú: Ṣemaiah àkọ́bí, Jehosabadi ẹlẹ́ẹ̀kejì, Joah ẹlẹ́ẹ̀kẹta, Sakari ẹlẹ́ẹ̀kẹrin, Netaneli ẹlẹ́ẹ̀karùnún,

5Ammieli ẹ̀kẹfà, Isakari èkeje àti Peulltai ẹ̀kẹjọ. (Nítorí tí Ọlọ́run ti bùkún Obedi-Edomu).

6Ọmọ rẹ̀ Ṣemaiah ní àwọn ọmọkùnrin pẹ̀lú tí wọ́n jẹ́ olórí ní ìdílé baba a wọn nítorí wọ́n jẹ́ ọkùnrin tó lágbára.

7Àwọn ọmọ Ṣemaiah: Otni, Refaeli, Obedi àti Elsabadi; àwọn ìbátan rẹ̀ Elihu àti Samakiah jẹ́ ọkùnrin alágbára.

8Gbogbo wọ̀nyí ní ìran ọmọ Obedi-Edomu; àwọn àti ọmọkùnrin àti ìbátan wọn jẹ́ alágbára ọkùnrin pẹ̀lú ipá láti ṣe ìsìn náà. Ìran Obedi-Edomu méjìlélọ́gọ́ta ni gbogbo rẹ̀.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.