15Èkejìlá fún oṣù kejìlá jẹ́ Heldai ará Netofa láti ìdílé Otnieli. Ẹgbàá méjìlá (24,000) ọkùnrin ni ó wà ní ìpín tirẹ̀.
16Àwọn ìjòyè lórí àwọn ẹ̀yà tí Israẹli: lórí àwọn ará Reubeni: Elieseri ọmọ Sikri; lórí àwọn ọmọ Simeoni: Ṣefatia ọmọ Maaka;
17lórí Lefi: Haṣabiah ọmọ Kemueli; lórí Aaroni: Sadoku;
18lórí Juda: Elihu arákùnrin Dafidi; lórí Isakari: Omri ọmọ Mikaeli;
19lórí Sebuluni: Iṣmaiah ọmọ Obadiah; lórí Naftali: Jerimoti ọmọ Asrieli;