13Àwọn ọmọ Kenasi: Otnieli àti Seraiah. Àwọn ọmọ Otnieli: Hatati àti Meonotai.
14Meonotai sì ni baba Ofira. Seraiah sì jẹ́ baba Joabu, baba Geharaṣinu. A pè báyìí nítorí àwọn ènìyàn àwọn oníṣọ̀nà ní ìwọ̀n.
15Àwọn ọmọ Kalebu ọmọ Jefunne: Iru, Ela, àti Naamu. Àwọn ọmọ Ela: Kenasi.
16Àwọn ọmọ Jehaleeli: Sifi, àti Sifa, Tiria àti Asareeli.
17Àwọn ọmọ Esra: Jeteri, Meredi, Eferi àti Jaloni. Ọ̀kan lára àwọn aya Meredi sì bí Miriamu, Ṣammai àti Iṣba baba Eṣitemoa.