1Àwọn ọmọ Juda: Peresi, Hesroni, Karmi, Huri àti Ṣobali.
2Reaiah ọmọ Ṣobali ni baba Jahati, àti Jahati baba Ahumai àti Lahadi. Àwọn wọ̀nyí ni ẹ̀yà ará Sorati.
3Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Etamu: Jesreeli, Iṣima, Idbaṣi, orúkọ arábìnrin wọn sì ni Haseleponi
4Penueli sì ni baba Gedori, àti Eseri baba Huṣa. Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Huri, àkọ́bí Efrata àti baba Bẹtilẹhẹmu.