32Wọ́n jíṣẹ́ pẹ̀lú orin níwájú àgọ́ ìpàdé títí tí Solomoni fi kọ́ ilé Olúwa ní Jerusalẹmu. Wọ́n ṣe iṣẹ́ ìsìn wọn ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà tí a fi lélẹ̀ fún wọn.
33Wọ̀nyí ni àwọn ọkùnrin tí ó sìn pẹ̀lú ọmọ wọn. Láti ọ̀dọ̀ àwọn ará Kohati: Hemani olùkọrin, ọmọ Joẹli, ọmọ Samuẹli,
34ọmọ Elkana, ọmọ Jerohamu, ọmọ Elieli, ọmọ Toha,
35ọmọ Sufu, ọmọ Elkana, ọmọ Mahati, ọmọ Amasai,
36ọmọ Elkana, ọmọ Joẹli, ọmọ Asariah, ọmọ Sefaniah,