14Ní ti àwọn ará Lefi: Ṣemaiah ọmọ Haṣubu, ọmọ Asrikamu, ọmọ Haṣabiah ará Merari;
15Bakibakari, Hereṣi, Galali àti Mattaniah, ọmọ Mika, ọmọ Sikri, ọmọ Asafu;
16Obadiah ọmọ Ṣemaiah, ọmọ Galali, ọmọ Jedutuni; àti Berekiah ọmọ Asa, ọmọ Elkana, tí ó ń gbé nínú àwọn ìlú àwọn ará Netofa.
17Àwọn olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà: Ṣallumu, Akkubu, Talmoni, Ahimani àti arákùnrin wọn, Ṣalumu olóyè wọn,
18ti wà ní ipò ìdúró ní ẹnu-ọ̀nà ọba ní apá ìhà ìlà-oòrùn títí di àkókò yí. Wọ̀nyí ni àwọn olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà tí ó jẹ́ ti ìpàgọ́ àwọn ará Lefi.