6Ní ti ará Sera: Jeueli. Àwọn ènìyàn láti Juda sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ó dín mẹ́wàá (690).
7Àti nínú àwọn ọmọ Benjamini ni: Sallu ọmọ Meṣullamu, ọmọ Hodafiah; ọmọ Hasenuah;
8Ibinaiah ọmọ Jerohamu; Ela ọmọ Ussi, ọmọ Mikri; àti Meṣullamu ọmọ Ṣefatia; ọmọ Reueli, ọmọ Ibinijah.
9Àwọn ènìyàn láti Benjamini gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe kọ ọ́ nínú ìran wọn nínú ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn, tí ó jẹ́ ẹgbẹ̀rún ó dín mẹ́rìnlélógójì (956). Gbogbo àwọn ọkùnrin yí jẹ́ àwọn olórí àwọn ìdílé.
10Ní ti àwọn àlùfáà: Jedaiah; Jehoiaribi; Jakini;