10Nísinsin yìí ó wà ní ọkàn mi láti bá Olúwa Ọlọ́run Israẹli dá májẹ̀mú. Bẹ́ẹ̀ ni kí ìbínú rẹ̀ kíkan kí ó lè yípadà kúrò lọ́dọ̀ wa.
11Àwọn ọmọ mi, ẹ má ṣe jáfara nísinsin yìí, nítorí tí Olúwa ti yàn yín láti dúró níwájú rẹ̀ láti sin, kí ẹ sì máa ṣe ìránṣẹ́ níwájú rẹ̀ àti láti sun tùràrí.”
12Nígbà náà àwọn ọmọ Lefi wọ̀nyí múra láti ṣe iṣẹ́: nínú àwọn ọmọ Kohati, Mahati ọmọ Amasai: àti Joẹli ọmọ Asariah; nínú àwọn ọmọ Merari, Kiṣi ọmọ Abdi àti Asariah ọmọ Jehaleeli; nínú àwọn ọmọ Gerṣoni, Joah, ọmọ Simma àti Edeni ọmọ Joah;
13nínú àwọn ọmọ Elisafani, Ṣimri àti Jeieli; nínú àwọn ọmọ Asafu, Sekariah àti Mattaniah;
14nínú àwọn ọmọ Hemani, Jehieli àti Ṣimei; nínú àwọn ọmọ Jedutuni, Ṣemaiah àti Usieli.