8Nítorí náà, ìbínú Olúwa ti ru sókè wá sórí Juda àti Jerusalẹmu ó sì ti fi wọ́n ṣe ohun èlò fún wàhálà, àti ìdààmú àti ẹ̀sín, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe fi ojú rẹ̀ rí i.
9Ìdí nìyí tí àwọn baba wa ṣe ṣubú nípa idà àti ìdí tí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin àti àwọn aya wa tiwọn kó wọ́n ní ìgbèkùn.
10Nísinsin yìí ó wà ní ọkàn mi láti bá Olúwa Ọlọ́run Israẹli dá májẹ̀mú. Bẹ́ẹ̀ ni kí ìbínú rẹ̀ kíkan kí ó lè yípadà kúrò lọ́dọ̀ wa.
11Àwọn ọmọ mi, ẹ má ṣe jáfara nísinsin yìí, nítorí tí Olúwa ti yàn yín láti dúró níwájú rẹ̀ láti sin, kí ẹ sì máa ṣe ìránṣẹ́ níwájú rẹ̀ àti láti sun tùràrí.”
12Nígbà náà àwọn ọmọ Lefi wọ̀nyí múra láti ṣe iṣẹ́: nínú àwọn ọmọ Kohati, Mahati ọmọ Amasai: àti Joẹli ọmọ Asariah; nínú àwọn ọmọ Merari, Kiṣi ọmọ Abdi àti Asariah ọmọ Jehaleeli; nínú àwọn ọmọ Gerṣoni, Joah, ọmọ Simma àti Edeni ọmọ Joah;