12“Ṣùgbọ́n ẹ̀yin fún àwọn Nasiri ní ọtí mu e sì pàṣẹ fún àwọn wòlíì kí wọ́n má ṣe sọtẹ́lẹ̀.
13“Ní báyìí, èmi yóò tẹ̀ yín mọ́lẹ̀ bí kẹ̀kẹ́ tí ó kún fún ìtí ti í tẹ̀.
14Ẹni tí ó yára bí àṣá kò ní rí ọ̀nà àbáyọ alágbára kò ní le è dúró lé agbára rẹ̀ jagunjagun kì yóò le gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là.
15Tafàtafà kì yóò dúró lórí ẹsẹ̀ rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó gún ẹṣin kì yóò gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là.
16Àní jagunjagun tí ó gbóyà jùlọ yóò sálọ ní ìhòhò ní ọjọ́ náà,” ni Olúwa wí.