Amosi 9

Mo rí Olúwa, ó dúró ní ẹ̀bá pẹpẹ, ó sì wí pé: “Lu orí àwọn àtẹ́rígbà ìlẹ̀kùn kí àwọn òpó kí ó lè mì fọ́ wọn sí orí àwọn gbogbo ènìyàn àwọn tí ó ṣẹ́kù ni èmi yóò fi idà pa, ẹni tí ó sálọ nínú wọn kí yóò sá gbé, ẹni ti ó sá àsálà nínú wọn kí yóò gbàlà.

Amos 9:1 (UKJV) I saw the LORD standing upon the altar: and he said, Strike the lintel of the door, that the posts may shake: and cut them in the head, all of them; and I will slay the last of them with the sword: he that flees of them shall not flee away, and he that escapes of them shall not be delivered.

1Mo rí Olúwa, ó dúró ní ẹ̀bá pẹpẹ, ó sì wí pé: “Lu orí àwọn àtẹ́rígbà ìlẹ̀kùn kí àwọn òpó kí ó lè mì fọ́ wọn sí orí àwọn gbogbo ènìyàn àwọn tí ó ṣẹ́kù ni èmi yóò fi idà pa, ẹni tí ó sálọ nínú wọn kí yóò sá gbé, ẹni ti ó sá àsálà nínú wọn kí yóò gbàlà.

2Bí wọ́n tilẹ̀ wa ilẹ̀ lọ sí ipò òkú, láti ibẹ̀ ni ọwọ́ mi yóò ti tẹ̀ wọ́n. Bí wọ́n tilẹ̀ gun òkè ọ̀run lọ, láti ibẹ̀ ni èmi yóò ti mú wọn sọ̀kalẹ̀.

3Bí wọ́n tilẹ̀ fi ara wọn pamọ́ ni orí òkè Karmeli, èmi yóò wá wọn rí, Èmi yóò si mú wọn kúrò níbẹ̀. Bí wọ́n tilẹ̀ fi ara pamọ́ fún mi sí ìsàlẹ̀ Òkun, láti ibẹ̀ ni Èmi yóò ti pàṣẹ fún ejò kí ó bù wọ́n ṣán.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.