Deuteronomi 28

Ègún ni fún agbọ̀n rẹ àti ọpọ́n ìpo-fúláwà rẹ.

Deuteronomy 28:17 (UKJV) Cursed shall be your basket and your store.

15Ṣùgbọ́n bí o kò bá gbọ́ ti Olúwa Ọlọ́run rẹ kí o sì rọra máa tẹ̀lé gbogbo àṣẹ àti òfin rẹ̀ tí mò ń fún ọ lónìí, gbogbo ègún yìí yóò wá sórí rẹ yóò sì máa bá ọ lọ.

16Ègún ni fún ọ ní ìlú, ègún ni fún ọ ní oko.

17Ègún ni fún agbọ̀n rẹ àti ọpọ́n ìpo-fúláwà rẹ.

18Ègún ni fún ọmọ inú rẹ, àti èso ilẹ̀ rẹ, ìbísí màlúù rẹ àti ọmọ àgùntàn rẹ.

19Ègún ni fún ọ nígbà tí o bá wọlé ègún sì ni fún ọ nígbà tí ìwọ bá jáde.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.