20Amramu sì fẹ́ Jokebedi arábìnrin baba rẹ̀ ní ìyàwó. Jokebedi sì bí Aaroni àti Mose fún un. Amramu lo ẹ̀tàdínlógóje (137) ọdún láyé.
21Àwọn ọmọ Isari ni: Kora, Nefegi àti Sikri.
22Àwọn ọmọ Usieli ni: Miṣaeli, Elsafani àti Sitiri.
23Aaroni fẹ́ Eliṣeba ọmọbìnrin Amminadabu tí í ṣe arábìnrin Nahiṣoni, ó sì bí Nadabu, Abihu, Eleasari àti Itamari.
24Àwọn ọmọ Kora ni: Asiri, Elkana àti Abiasafu. Ìwọ̀nyí ni ìran Kora.