Esekiẹli 32

Ní ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún oṣù, ọdún kejìlá, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ mí wá:

Ezekiel 32:17 (UKJV) It came to pass also in the twelfth year, in the fifteenth day of the month, that the word of the LORD came unto me, saying,

15Nígbà tí mo bá sọ Ejibiti di ahoro, tí mo sì kó gbogbo ohun tí ó wà ní orí ilẹ̀ náà kúrò. Nígbà tí mo bá gé àwọn olùgbé ibẹ̀ lulẹ̀, nígbà náà wọn yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa.’

16“Èyí yìí ni ẹkún tí a yóò sun fún un. Àwọn ọmọbìnrin orílẹ̀-èdè yóò sun ún; nítorí Ejibiti àti gbogbo ìjọ rẹ, wọn yóò sun ún, ní Olúwa Olódùmarè wí.”

17Ní ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún oṣù, ọdún kejìlá, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ mí wá:

18“Ọmọ ènìyàn, pohùnréré ẹkún lórí Ejibiti kí o sì ránṣẹ́ sí ìsàlẹ̀ ilẹ̀ àti òun àti àwọn ọmọbìnrin orílẹ̀-èdè alágbára, pẹ̀lú àwọn tí o lọ sí ìsàlẹ̀, kòtò.

19Sọ fún wọn, ‘Ǹjẹ́ ìwọ ní ojúrere jù àwọn tí o kù lọ? Lọ sí ìsàlẹ̀ kí a sì tẹ́ ọ sí àárín àwọn aláìkọlà náà.’

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.