Esekiẹli 32

Nígbà tí mo bá sọ Ejibiti di ahoro, tí mo sì kó gbogbo ohun tí ó wà ní orí ilẹ̀ náà kúrò. Nígbà tí mo bá gé àwọn olùgbé ibẹ̀ lulẹ̀, nígbà náà wọn yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa.’

Ezekiel 32:15 (UKJV) When I shall make the land of Egypt desolate, and the country shall be destitute of that whereof it was full, when I shall strike all them that dwell therein, then shall they know that I am the LORD.

13Gbogbo ẹran ọ̀sìn rẹ ni èmi yóò parun ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi kì i ṣe ẹsẹ̀ ènìyàn ní yóò tẹ ibẹ̀ ẹsẹ̀ ẹran ọ̀sìn kì yóò sì mú kí ibẹ̀ ni ẹrọ̀fọ̀.

14Lẹ́yìn náà èmi yóò mú kí omi rẹ̀ tòrò kí àwọn odò rẹ̀ kí o sàn bí epo, ni Olúwa Olódùmarè wí.

15Nígbà tí mo bá sọ Ejibiti di ahoro, tí mo sì kó gbogbo ohun tí ó wà ní orí ilẹ̀ náà kúrò. Nígbà tí mo bá gé àwọn olùgbé ibẹ̀ lulẹ̀, nígbà náà wọn yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa.’

16“Èyí yìí ni ẹkún tí a yóò sun fún un. Àwọn ọmọbìnrin orílẹ̀-èdè yóò sun ún; nítorí Ejibiti àti gbogbo ìjọ rẹ, wọn yóò sun ún, ní Olúwa Olódùmarè wí.”

17Ní ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún oṣù, ọdún kejìlá, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ mí wá:

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.