1Wọ̀nyí ni àwọn olórí ìdílé àti àwọn tí ó fi orúkọ sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn tì wọn gòkè pẹ̀lú mi láti Babeli ní àkókò ìjọba Artasasta ọba:
2nínú àwọn ọmọ Finehasi: Gerṣomu; nínú àwọn ọmọ Itamari: Daniẹli; nínú àwọn ọmọ Dafidi: Hattusi,
3nínú àwọn ọmọ Ṣekaniah; nínú àwọn ọmọ Paroṣi: Sekariah, àti pé àádọ́jọ ọkùnrin fi orúkọ sílẹ̀ pẹ̀lú rẹ;
4nínú àwọn ọmọ Pahati-Moabu: Elihoenai ọmọ Serahiah àti àwọn igba ọkùnrin pẹ̀lú rẹ̀;
5nínú àwọn ọmọ Sattu: Ṣekaniah ọmọ Jahasieli àti àwọn ọ̀ọ́dúnrún (300) ọkùnrin pẹ̀lú rẹ̀;