Gẹnẹsisi 11

Nígbà tí Arfakṣadi pé ọdún márùndínlógójì ni ó bí Ṣela.

Genesis 11:12 (UKJV) And Arphaxad lived five and thirty years, and brings forth Salah:

10Wọ̀nyí ni ìran Ṣemu. Ọdún méjì lẹ́yìn ìkún omi, tí Ṣemu pé ọgọ́rùn-ún ọdún ni ó bí Arfakṣadi.

11Lẹ́yìn tí ó bí Arfakṣadi, Ṣemu tún wà láààyè fún ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọdún (500), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn.

12Nígbà tí Arfakṣadi pé ọdún márùndínlógójì ni ó bí Ṣela.

13Arfakṣadi sì wà láààyè fún ọdún mẹ́tàlénírinwó (403) lẹ́yìn tí ó bí Ṣela, ó sì bí àwọn ọmọbìnrin àti àwọn ọmọkùnrin mìíràn.

14Nígbà tí Ṣela pé ọmọ ọgbọ̀n ọdún ni ó bí Eberi.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.