2Olúwa mo tí gbọ́ ohùn rẹ; ẹ̀rù sì ba mi fún iṣẹ́ rẹ Olúwa sọ wọn di ọ̀tún ní ọjọ́ ti wa, ní àkókò tiwa, jẹ́ kó di mí mọ̀; ni ìbínú, rántí àánú.
3Ọlọ́run yóò wa láti Temani, ibi mímọ́ jùlọ láti òkè Parani ògo rẹ̀ sí bo àwọn ọ̀run, ilé ayé sì kún fún ìyìn rẹ.
4Dídán rẹ sí dàbí ìmọ́lẹ̀ oòrùn ìtànṣán ìmọ́lẹ̀ jáde wa láti ọwọ́ rẹ, níbi tí wọn fi agbára rẹ̀ pamọ́ sí.
5Àjàkálẹ̀-ààrùn ń lọ ni iwájú rẹ; ìyọnu sí ń tọ ẹsẹ̀ rẹ lọ.
6Ó dúró, ó sì mi ayé; ó wò, ó sì mú àwọn orílẹ̀-èdè wárìrì a sì tú àwọn òkè ńlá ayérayé ká, àwọn òkè kéékèèké ayérayé sì tẹríba: ọ̀nà rẹ ayérayé ni.