10Wọn yóò máa tẹ̀lé Olúwa; òun yóò bú ramúramù bí i kìnnìún. Nígbà tó bá bú, àwọn ọmọ rẹ yóò wá ní ìwárìrì láti ìwọ̀-oòrùn.
11Wọn ó wá pẹ̀lú ẹ̀rù bí i ẹyẹ láti Ejibiti, bí i àdàbà láti Asiria, Èmi ó mú wọn padà sí ilé wọn,” ni Olúwa wí.
12Efraimu tí fi irọ́ yí mi ká ilé Israẹli pẹ̀lú ẹ̀tàn. Ṣùgbọ́n Juda sì dúró ṣinṣin pẹ̀lú Ọlọ́run. Ó sì ṣe olóòtítọ́ sí Ẹni mímọ́ Israẹli.