Hosea 2

Èmi yóò pa àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀ run, èyí tí ó pè ní èrè rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn olólùfẹ́ rẹ̀, Èmi yóò sọ wọ́n di igbó, àwọn ẹranko búburú yóò sì jẹ́ wọn run.

Hosea 2:12 (UKJV) And I will destroy her vines and her fig trees, whereof she has said, These are my rewards that my lovers have given me: and I will make them a forest, and the beasts of the field shall eat them.

10Èmi yóò sì fi ìwà ìtìjú rẹ̀ hàn lójú àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ kò sí ẹni tí yóò gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ mi,

11Èmi yóò mú gbogbo ayọ̀ rẹ̀ wá sí òpin: àjọ̀dún ọdọọdún rẹ̀, oṣù tuntun rẹ̀, ọjọ́ ìsinmi, àti gbogbo àwọn àjọ̀dún tí a yàn.

12Èmi yóò pa àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀ run, èyí tí ó pè ní èrè rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn olólùfẹ́ rẹ̀, Èmi yóò sọ wọ́n di igbó, àwọn ẹranko búburú yóò sì jẹ́ wọn run.

13Èmi yóò bẹ̀ ọjọ́ Baalimu wò ní ara rẹ̀ nínú èyí tó ń fi tùràrí jóná fún Baali; tí ó fi òrùka etí àti ohun ọ̀ṣọ́ rẹ̀, ṣe ara rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́, tó sì tẹ̀lé àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ lọ. Ṣùgbọ́n èmi ni òun gbàgbé,” ni Olúwa wí.

14“Nítorí náà, èmi yóò tàn án, Èmi ó sì mú u lọ sí ilẹ̀ aṣálẹ̀, Èmi ó fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ bá a sọ̀rọ̀

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.