Hosea 2

“Èmi yóò sì dáhùn ní ọjọ́ náà,” ni Olúwa wí; “Èmi yóò dá àwọn ọ̀run lóhùn àwọn ọ̀run yóò sì dá ilẹ̀ lóhùn;

Hosea 2:21 (UKJV) And it shall come to pass in that day, I will hear, says the LORD, I will hear the heavens, and they shall hear the earth;

19Èmi yóò fẹ́ ọ fún ara mi títí láé; Èmi ó fẹ́ ọ ní ìwà òdodo àti òtítọ́, ní ìfẹ́ àti àánú.

20Èmi yóò fẹ́ ọ fún ara mi ní òtítọ́ ìwọ yóò sì mọ Olúwa.

21“Èmi yóò sì dáhùn ní ọjọ́ náà,” ni Olúwa wí; “Èmi yóò dá àwọn ọ̀run lóhùn àwọn ọ̀run yóò sì dá ilẹ̀ lóhùn;

22ilẹ̀ náà yóò sì dá ọkà, wáìnì tuntun àti òróró lóhùn Gbogbo wọn ó sì dá Jesreeli lóhùn.

23Èmi ó sì gbìn ín fún ara mi lórí ilẹ̀ náà, Èmi yóò ṣàánú fún ẹni tí kò tì í ri ‘Àánú gbà.’ Èmi yóò sọ fún àwọn tí ‘Kì í ṣe ènìyàn mi pé,’ ‘Ẹ̀yin ni ènìyàn mi’; àwọn náà yóò sì wí pé, ‘Ìwọ ni Ọlọ́run mi.’ ”

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.