Hosea 2

Nítorí náà, èmi ó fi ẹ̀gún dì í lọ́nà, Èmi ó mọ odi yí i ká kí ó má ba à rọ́nà lọ.

Hosea 2:6 (UKJV) Therefore, behold, I will hedge up your way with thorns, and make a wall, that she shall not find her paths.

4Èmi kò ní fi àánú mi hàn sí àwọn ọmọ rẹ̀ nítorí ọmọ àgbèrè ni wọ́n jẹ́.

5Nítorí ìyá wọn ti hùwà àgbèrè, ó sì lóyún wọn nínú ìtìjú. Ó wí pé, ‘Èmi ó tún tọ́ àwọn àyànfẹ́ mi lẹ́yìn, tó ń fún mi ní oúnjẹ àti omi, ní irun àgùntàn mi àti ọ̀gbọ̀ mi, òróró mi àti ohun mímu mi.’

6Nítorí náà, èmi ó fi ẹ̀gún dì í lọ́nà, Èmi ó mọ odi yí i ká kí ó má ba à rọ́nà lọ.

7Yóò sáré lé àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ ṣùgbọ́n kò ní bá wọn; yóò wá wọn ṣùgbọ́n kò ní rí wọn. Nígbà náà ni yóò sọ pé, ‘Èmi ó padà sí ọ̀dọ̀ ọkọ mi àkọ́kọ́ nítorí pé ó dára fún mi nígbà náà ju ìsinsin yìí lọ.’

8Nítorí pé kò tí ì mọ̀ pé èmi ni àti ẹni tó fún un ní ọkà, ọtí wáìnì tuntun àti òróró ẹni tí ó fún un ní fàdákà àti wúrà lọ́pọ̀lọ́pọ̀, èyí tí wọ́n lò fún Baali.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.