Hosea 2

Nítorí pé kò tí ì mọ̀ pé èmi ni àti ẹni tó fún un ní ọkà, ọtí wáìnì tuntun àti òróró ẹni tí ó fún un ní fàdákà àti wúrà lọ́pọ̀lọ́pọ̀, èyí tí wọ́n lò fún Baali.

Hosea 2:8 (UKJV) For she did not know that I gave her corn, and wine, and oil, and multiplied her silver and gold, which they prepared for Baal.

6Nítorí náà, èmi ó fi ẹ̀gún dì í lọ́nà, Èmi ó mọ odi yí i ká kí ó má ba à rọ́nà lọ.

7Yóò sáré lé àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ ṣùgbọ́n kò ní bá wọn; yóò wá wọn ṣùgbọ́n kò ní rí wọn. Nígbà náà ni yóò sọ pé, ‘Èmi ó padà sí ọ̀dọ̀ ọkọ mi àkọ́kọ́ nítorí pé ó dára fún mi nígbà náà ju ìsinsin yìí lọ.’

8Nítorí pé kò tí ì mọ̀ pé èmi ni àti ẹni tó fún un ní ọkà, ọtí wáìnì tuntun àti òróró ẹni tí ó fún un ní fàdákà àti wúrà lọ́pọ̀lọ́pọ̀, èyí tí wọ́n lò fún Baali.

9“Nítorí náà, èmi yóò mú ọkà mi kúrò nígbà tó bá pọ́n, èmi yóò sì mú wáìnì mi kúrò ní àsìkò rẹ̀. Èmi yóò sì gba irun àgùntàn àti ọ̀gbọ̀ mi padà ti mo ti fi fún un láti bo ìhòhò rẹ̀.

10Èmi yóò sì fi ìwà ìtìjú rẹ̀ hàn lójú àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ kò sí ẹni tí yóò gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ mi,

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.