Hosea 7

“Efraimu ti darapọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn náà; Efraimu jẹ́ àkàrà tí a kò yípadà.

Hosea 7:8 (UKJV) Ephraim, he has mixed himself among the people; Ephraim is a cake not turned.

6Ọkàn wọn ń gbóná bí i ààrò wọ́n sì tọ̀ ọ́ lọ pẹ̀lú rìkíṣí, ìbínú wọn pa lọ́lọ́ ní gbogbo òru ó sì bú jáde bí ọ̀wọ́-iná ní òwúrọ̀.

7Gbogbo wọn gbóná bí ààrò wọ́n pa gbogbo olórí wọn run, gbogbo ọba wọn si ṣubú kò sì ṣí ẹnìkan nínú wọn tí ó ké pè mí.

8“Efraimu ti darapọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn náà; Efraimu jẹ́ àkàrà tí a kò yípadà.

9Àwọn àlejò ti jẹ agbára rẹ̀ run ṣùgbọ́n kò sì mọ̀. Ewú ti wà ní orí rẹ̀ káàkiri bẹ́ẹ̀ ni kò kíyèsi i.

10Ìgbéraga Israẹli ń jẹ́rìí sí i ṣùgbọ́n pẹ̀lú gbogbo èyí kò padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa Ọlọ́run, tàbí kí ó wá a.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.