31Madmena ti fẹsẹ̀ fẹ́ ẹ, àwọn ènìyàn Gebimu ti fi ara pamọ́.
32Ní ọjọ́ yìí, wọn yóò dúró ní Nobu wọn yóò kan sáárá, ní òkè ọmọbìnrin Sioni ní òkè Jerusalẹmu.
33Wò ó, Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun, yóò kán ẹ̀ka náà sọnù pẹ̀lú agbára. Àwọn igi ọlọ́lá ni a ó gé lulẹ̀ àwọn tí ó ga gogoro ni a ó rẹ̀ sílẹ̀.
34Òun yóò gé igbó dídí pẹ̀lú àáké, Lebanoni yóò ṣubú níwájú Alágbára náà.