Isaiah 11

Ọ̀nà gidi yóò wà fún àwọn ènìyàn an rẹ̀ tí ó ṣẹ́kù tí ó kù sílẹ̀ ní Asiria, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà fún Israẹli nígbà tí wọ́n gòkè láti Ejibiti wá.

Isaiah 11:16 (UKJV) And there shall be an highway for the remnant of his people, which shall be left, from Assyria; like it was to Israel in the day that he came up out of the land of Egypt.

14Wọn yóò fò mọ́ èjìká Filistini sí apá ìwọ̀-oòrùn, wọn yóò pawọ́pọ̀ kọlu àwọn ènìyàn apá ìlà-oòrùn. Wọn yóò gbé ọwọ́ wọn lé Edomu àti Moabu, àwọn ará Ammoni yóò sì di ìwẹ̀fà wọn.

15Olúwa yóò sọ di gbígbé àyasí Òkun Ejibiti, pẹ̀lú atẹ́gùn gbígbóná ni yóò na ọwọ́ rẹ̀, kọjá lórí odò Eufurate. Òun yóò sì sọ ọ́ di ọmọdò méje tó fi jẹ́ pé àwọn ènìyàn yóò máa là á kọjá pẹ̀lú bàtà.

16Ọ̀nà gidi yóò wà fún àwọn ènìyàn an rẹ̀ tí ó ṣẹ́kù tí ó kù sílẹ̀ ní Asiria, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà fún Israẹli nígbà tí wọ́n gòkè láti Ejibiti wá.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.