Isaiah 22

Kí ni ohun tí ò ń ṣe níhìn-ín yìí àti pé ta ni ó sì fún ọ ní àṣẹ láti gbẹ́ ibojì kan fún ara rẹ níhìn-ín yìí, tí ó gbẹ́ ibojì ní ibi gíga tí ó sì gbẹ́ ibi ìsinmi rẹ nínú àpáta?

Isaiah 22:16 (UKJV) What have you here? and whom have you here, that you have hewed you out a tomb here, as he that hews him out a tomb on high, and that graves an habitation for himself in a rock?

14Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti sọ èyí di mí mọ̀ létí ì mi: “Títí di ọjọ́ ikú yín a kò ní ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ yìí,” ni Olúwa wí, àní Olúwa àwọn ọmọ-ogun.

15Èyí ni ohun tí Olúwa, àní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, “Lọ, sọ fún ìríjú yìí pé, fún Ṣebna, ẹni tí ààfin wà ní ìkáwọ́ rẹ̀.

16Kí ni ohun tí ò ń ṣe níhìn-ín yìí àti pé ta ni ó sì fún ọ ní àṣẹ láti gbẹ́ ibojì kan fún ara rẹ níhìn-ín yìí, tí ó gbẹ́ ibojì ní ibi gíga tí ó sì gbẹ́ ibi ìsinmi rẹ nínú àpáta?

17“Kíyèsára, Olúwa fẹ́ gbá ọ mú gírígírí kí ó sì jù ọ́ nù, ìwọ ọkùnrin alágbára.

18Òun yóò ká ọ rúgúdù bí i òkìtì yóò sì sọ ọ́ sí orílẹ̀-èdè ńlá kan. Níbẹ̀ ni ìwọ yóò sì kú sí àti níbẹ̀ pẹ̀lú ni àwọn kẹ̀kẹ́ ogun àràmọ̀ǹdà rẹ yóò wà— ìwọ di ìtìjú sí ilé ọ̀gá rẹ!

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.