Isaiah 25

Wọn yóò na ọwọ́ wọn jáde nínú rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí òmùwẹ̀ tí ń na ọwọ́ rẹ̀ jáde láti lúwẹ̀ẹ́. Ọlọ́run yóò mú ìgbéraga wọn wálẹ̀ bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìṣeféfé wà ní ọwọ́ wọn.

Isaiah 25:11 (UKJV) And he shall spread forth his hands in the midst of them, as he that swins spreads forth his hands to swim: and he shall bring down their pride together with the spoils of their hands.

9Ní ọjọ́ náà wọn yóò sọ pé, “Nítòótọ́ eléyìí ni Ọlọ́run wa; àwa ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú rẹ̀, òun sì gbà wá là. Èyí ni Olúwa, àwa gbẹ́kẹ̀lé e, ẹ jẹ́ kí a yọ̀ kí inú wa sì dùn nínú ìgbàlà rẹ̀.”

10Ọwọ́ Olúwa yóò sinmi lé orí òkè yìí ṣùgbọ́n a ó tẹ Moabu mọ́lẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀; gẹ́gẹ́ bí a ti gún koríko mọ́lẹ̀ di ajílẹ̀.

11Wọn yóò na ọwọ́ wọn jáde nínú rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí òmùwẹ̀ tí ń na ọwọ́ rẹ̀ jáde láti lúwẹ̀ẹ́. Ọlọ́run yóò mú ìgbéraga wọn wálẹ̀ bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìṣeféfé wà ní ọwọ́ wọn.

12Òun yóò sì bi gbogbo ògiri gíga alágbára yín lulẹ̀ wọn yóò sì wà nílẹ̀, Òun yóò sì mú wọn wá si ilẹ̀, àní sí erùpẹ̀ lásán.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.