17Èmi yóò fi ìdájọ́ ṣe okùn òsùwọ̀n àti òdodo òjé òsùwọ̀n; yìnyín yóò gbá ààbò yín dànù àti irọ́, omi yóò sì kún bo gbogbo ibi tí ẹ ń fi ara pamọ́ sí mọ́lẹ̀.
18Májẹ̀mú yín tí ẹ bá ikú dá ni a ó fa igi lé; àdéhùn yín pẹ̀lú ibojì ni kì yóò dúró. Nígbà tí ìbínú gbígbóná náà bá fẹ́ kọjá, a ó ti ipa rẹ̀ lù yín bolẹ̀.
19Nígbàkígbà tí ó bá ti wá ni yóò máa gbé ọ lọ, ni àràárọ̀, ní ọ̀sán àti ní òru, ni yóò máa fẹ́ kọjá lọ.” Ìmòye ọ̀rọ̀-ìmọ̀ yìí yóò máa mú ìpayà ńlá wá.
20Ibùsùn kúrú púpọ̀ fún ìnara lé lórí, ìbora kò fẹ̀ tó láti yí ara yín ká.
21Olúwa yóò dìde sókè gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ní òkè Perasimu yóò ru ara rẹ̀ sókè gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ní àfonífojì Gibeoni— láti ṣe iṣẹ́ rẹ̀, abàmì iṣẹ́ ẹ rẹ̀, yóò ṣe iṣẹ́ rẹ̀, àní àjèjì iṣẹ́ rẹ̀.