Isaiah 28

Májẹ̀mú yín tí ẹ bá ikú dá ni a ó fa igi lé; àdéhùn yín pẹ̀lú ibojì ni kì yóò dúró. Nígbà tí ìbínú gbígbóná náà bá fẹ́ kọjá, a ó ti ipa rẹ̀ lù yín bolẹ̀.

Isaiah 28:18 (UKJV) And your covenant with death shall be disannulled, and your agreement with hell shall not stand; when the overflowing scourge shall pass through, then all of you shall be trodden down by it.

16Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: “Kíyèsi i, èmi gbé òkúta kan lélẹ̀ ní Sioni, òkúta tí a dánwò, òkúta igun ilé iyebíye fún ìpìlẹ̀ tí ó dájú; ẹnikẹ́ni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé kì yóò ní ìfòyà.

17Èmi yóò fi ìdájọ́ ṣe okùn òsùwọ̀n àti òdodo òjé òsùwọ̀n; yìnyín yóò gbá ààbò yín dànù àti irọ́, omi yóò sì kún bo gbogbo ibi tí ẹ ń fi ara pamọ́ sí mọ́lẹ̀.

18Májẹ̀mú yín tí ẹ bá ikú dá ni a ó fa igi lé; àdéhùn yín pẹ̀lú ibojì ni kì yóò dúró. Nígbà tí ìbínú gbígbóná náà bá fẹ́ kọjá, a ó ti ipa rẹ̀ lù yín bolẹ̀.

19Nígbàkígbà tí ó bá ti wá ni yóò máa gbé ọ lọ, ni àràárọ̀, ní ọ̀sán àti ní òru, ni yóò máa fẹ́ kọjá lọ.” Ìmòye ọ̀rọ̀-ìmọ̀ yìí yóò máa mú ìpayà ńlá wá.

20Ibùsùn kúrú púpọ̀ fún ìnara lé lórí, ìbora kò fẹ̀ tó láti yí ara yín ká.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.