Isaiah 29

Èmi yóò sì wà ní bùba yí ọ ká níbi gbogbo, Èmi yóò sì fi ilé ìṣọ́ yí ọ ká, Èmi yóò sì fi iṣẹ́ ìdó ti ni mi dojúkọ ọ́.

Isaiah 29:3 (UKJV) And I will camp against you round about, and will lay siege against you with a mount, and I will raise forts against you.

1Ègbé ni fún ọ, Arieli, Arieli, ìlú níbi tí Dafidi tẹ̀dó sí! Fi ọdún kún ọdún sì jẹ́ kí àwọn àkọlùkọgbà àjọ̀dún un rẹ tẹ̀síwájú.

2Síbẹ̀síbẹ̀ èmi yóò dó ti Arieli òun yóò ṣọ̀fọ̀ yóò sì sọkún, òun yóò sì dàbí pẹpẹ ọkàn sí mi.

3Èmi yóò sì wà ní bùba yí ọ ká níbi gbogbo, Èmi yóò sì fi ilé ìṣọ́ yí ọ ká, Èmi yóò sì fi iṣẹ́ ìdó ti ni mi dojúkọ ọ́.

4Ní ìrẹ̀sílẹ̀, ìwọ ó sì máa sọ̀rọ̀ láti ilẹ̀ wá; ọ̀rọ̀ rẹ yóò sì máa kùn jáde láti inú erùpẹ̀. Ohun rẹ yóò máa jáde bí i ti ẹnìkan tó ní ẹ̀mí àfọ̀ṣẹ láti ilẹ̀ jáde wá, láti inú erùpẹ̀ ni ohùn rẹ yóò máa wá wúyẹ́wúyẹ́.

5Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀tá rẹ, yóò dàbí yanrìn kíkúnná, agbo àwọn aláìláàánú bí ìyàngbò tí a fẹ́ dànù. Lójijì, ní ìṣẹ́jú kan,

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.