6Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò wá pẹ̀lú àrá àti ilẹ̀-rírì àti ariwo ńlá, àti ẹ̀fúùfù líle àti iná ajónirun.
7Lẹ́yìn náà, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ènìyàn tí gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó bá Arieli jà, tí ó dojú ìjà kọ òun àti ilé olódi rẹ̀ tí ó sì dó tì í, yóò dàbí ẹni pé nínú àlá, bí ìran ní òru
8àti bí ìgbà tí ẹni tí ebi ń pa ń lá àlá pé òun ń jẹun, ṣùgbọ́n ó jí, ebi rẹ̀ sì wà pẹ̀lú rẹ̀; tàbí bí ìgbà tí ẹni tí òǹgbẹ ń gbẹ lá àlá pé òun ń mu omi, ṣùgbọ́n nígbà tí ó jí, sì wò ó, ó dákú, òǹgbẹ sì ń gbẹ ọkàn rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni yóò sì rí fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè tí ń bá òkè Sioni jà.
9Ẹ bẹ̀rù kí ẹnu kí ó yà yín, ẹ fọ́ ara yín lójú kí ẹ má sì ríran; ẹ mutí yó kì í ṣe ọtí wáìnì, ẹ ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n, ṣùgbọ́n kì í ṣe ti ọtí líle.
10Olúwa ti mú oorun ìjìká wá sórí i yín: ó ti dì yín lójú ẹ̀yin wòlíì; ó ti bo orí yín ẹ̀yin aríran.