Isaiah 30

Ẹgba kọ̀ọ̀kan tí Olúwa bá gbé lé wọn pẹ̀lú ọ̀pá ìjẹníyà rẹ̀ yóò jẹ́ ti ṣaworo àti ti dùùrù, gẹ́gẹ́ bí ó ti ń bá wọn jà lójú ogun pẹ̀lú ìkùùkuu láti apá rẹ̀.

Isaiah 30:32 (UKJV) And in every place where the grounded staff shall pass, which the LORD shall lay upon him, it shall be with timbrels and harps: and in battles of shaking will he fight with it.

30Olúwa yóò jẹ́ kí wọn ó gbọ́ ohùn ògo rẹ̀ yóò sì jẹ́ kí wọ́n rí apá rẹ̀ tí ó ń bọ̀ wálẹ̀ pẹ̀lú ìbínú gbígbóná àti iná ajónirun, pẹ̀lú mọ̀nàmọ́ná, àrá àti yìnyín.

31Ohùn Olúwa yóò fọ́ Asiria túútúú, pẹ̀lú ọ̀pá aládé rẹ̀ ni yóò lù wọ́n bolẹ̀.

32Ẹgba kọ̀ọ̀kan tí Olúwa bá gbé lé wọn pẹ̀lú ọ̀pá ìjẹníyà rẹ̀ yóò jẹ́ ti ṣaworo àti ti dùùrù, gẹ́gẹ́ bí ó ti ń bá wọn jà lójú ogun pẹ̀lú ìkùùkuu láti apá rẹ̀.

33A ti tọ́jú Tofeti sílẹ̀ tipẹ́tipẹ́, a ti tọ́jú rẹ̀ sílẹ̀ fún ọba. Ojú ààrò rẹ̀ ni a ti gbẹ́ jì tí ó sì fẹ̀, pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ iná àti igi ìdáná; èémí Olúwa, gẹ́gẹ́ bí ìṣàn sulfuru ń jó ṣe mú un gbiná.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.