Isaiah 30

Bí àwọn olórí rẹ tilẹ̀ wà ní Ṣoani, tí àwọn ikọ̀ wọn sì ti dé sí Hanisi,

Isaiah 30:4 (UKJV) For his princes were at Zoan, and his ambassadors came to Hanes.

2tí wọ́n lọ sí Ejibiti láìṣe fún mi, tí ó ń wá ìrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ Farao fún ààbò, sí òjìji Ejibiti fún ibi ìsádi.

3Ṣùgbọ́n ààbò Farao yóò jásí ìtìjú fún un yín, òjìji Ejibiti yóò mú àbùkù bá a yín.

4Bí àwọn olórí rẹ tilẹ̀ wà ní Ṣoani, tí àwọn ikọ̀ wọn sì ti dé sí Hanisi,

5gbogbo wọn ni a ó dójútì, nítorí àwọn ènìyàn kan tí kò wúlò fún wọn, tí kò mú ìrànlọ́wọ́ tàbí àǹfààní wá, bí kò ṣe àbùkù àti ìdójúti ni.”

6Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ sí àwọn ẹranko tí ó wà ní gúúsù. Láàrín ilẹ̀ ìnira àti ìpọ́njú, ti kìnnìún àti abo kìnnìún ti paramọ́lẹ̀ àti ejò olóró, àwọn ikọ̀ náà kó ẹrù àti ọrọ̀ wọn lẹ́yìn àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àwọn ohun ìní wọn ní orí àwọn ìbákasẹ, sí orílẹ̀-èdè aláìlérè,

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.